Ọlọrun Ọba Atóbijù
1 OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀;
jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn.
2 Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká;
òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
3 Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀,
ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì.
4 Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé,
ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì.
5 Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA,
àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.
6 Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀.
7 Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa,
àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn;
gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀.
8 Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn.
Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀,
nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA.
9 Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,
o ju gbogbo ayé lọ,
a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.
10 Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;
OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,
a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.
11 Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,
ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.
12 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo,
kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.