Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 86

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi,

nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí.

2 Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí;

gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là;

ìwọ ni Ọlọrun mi.

3 Ṣàánú mi, OLUWA,

nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru.

4 Mú inú iranṣẹ rẹ dùn,

nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.

5 Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA,

o máa ń dárí jini;

ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

6 Fetí sí adura mi, OLUWA,

gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi.

7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́,

nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi.

8 OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa;

kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ.

9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá,

OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ:

wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo.

10 Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;

ìwọ nìkan ni Ọlọrun.

11 OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,

kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;

kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.

12 Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;

n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.

13 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;

o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú.

14 Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;

ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;

wọn kò sì bìkítà fún ọ.

15 Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;

o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.

16 Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;

fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;

kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là.

17 Fi àmì ojurere rẹ hàn mí,

kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i,

kí ojú sì tì wọ́n;

nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́,

tí o sì tù mí ninu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *