Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 83

Adura Ìṣẹ́gun

1 Ọlọrun, má dákẹ́;

má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́!

2 Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ;

àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ.

3 Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ;

wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́.

4 Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run;

kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!”

5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò;

wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.

6 Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli,

àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri,

7 àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki,

àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire.

8 Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn;

àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti.

9 Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani,

bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni,

10 àwọn tí o parun ní Endori,

tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀.

11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu;

ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna,

12 àwọn tí ó wí pé,

“Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrun

kí á sọ ọ́ di tiwa.”

13 Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé,

àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù.

14 Bí iná tíí jó igbó,

àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀,

15 bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn,

kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n.

16 Da ìtìjú bò wọ́n,

kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA.

17 Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae,

kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú.

18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan,

tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA,

ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *