Ògo OLUWA ati Ipò Eniyan
1 OLUWA, Oluwa wa,
orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!
Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run.
2 Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ,
wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀,
nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ,
kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀–
4 Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?
Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?
5 O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,
o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé.
6 O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó;
8 àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun,
ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun.
9 OLUWA, Oluwa wa,
orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!