Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 77

Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú

1 Mo ké pe Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́,

mo kígbe pe Ọlọrun kí ó lè gbọ́ tèmi.

2 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA;

ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀,

ṣugbọn n kò rí ìtùnú.

3 Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;

mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.

4 OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òru

mo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀.

5 Mo ranti ìgbà àtijọ́,

mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

6 Mo ronú jinlẹ̀ lóru,

mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò.

7 Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;

àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́?

8 Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;

àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata?

9 Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;

àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé?

10 Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni pé

Ọ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”

11 N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,

àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì.

12 N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;

n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

13 Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;

oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa?

14 Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;

o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan.

15 O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là;

àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu.

16 Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun,

àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́,

ẹ̀rù bà á;

ibú omi sì wárìrì.

17 Ìkùukùu da omi òjò sílẹ̀,

ojú ọ̀run sán ààrá;

mànàmáná ń kọ yẹ̀rì káàkiri.

18 Ààrá ń sán kíkankíkan ní ojú ọ̀run,

mànàmáná ń kọ yànràn, gbogbo ayé sì mọ́lẹ̀;

ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì.

19 Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun,

ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já;

sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.

20 O kó àwọn eniyan rẹ jáde bí agbo ẹran,

o fi Mose ati Aaroni ṣe olórí wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *