Adura Ìrànlọ́wọ́
1 Ọlọrun, dákun, gbà mí,
yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.
2 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mi
kí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn;
jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,
kí wọn sì tẹ́.
3 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bo
àwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi;
kí wọn sì gba èrè ìtìjú.
4 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ,
kí inú wọn sì máa dùn,
kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé,
“Ọlọrun tóbi!”
5 Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí,
yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun!
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi,
má pẹ́ OLÚWA.