Orin Ọpẹ́
1 Kí Ọlọrun óo ṣàánú wa, kí ó bukun wa;
kí ojú rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí wa lára;
2 kí gbogbo ayé lè mọ ọ̀nà rẹ̀;
kí gbogbo orílẹ̀-èdè sì mọ ìgbàlà rẹ̀.
3 Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;
jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!
4 Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn,
kí wọn ó máa kọrin ayọ̀,
nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju;
o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé.
5 Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;
jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!
6 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde;
Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa.
7 Ọlọrun bukun wa,
kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù rẹ̀.