Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 60

Adura fún Ìgbàlà

1 Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀,

o ti wó odi wa;

o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò.

2 O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì;

o ti mú kí ó yanu;

dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì.

3 O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira,

o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

4 O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,

kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá.

5 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,

fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa,

kí o sì dá wa lóhùn.

6 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,

ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,

n óo sì pín àfonífojì Sukotu.

7 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;

Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,

Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

8 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi;

lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé;

n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.”

9 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?

Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?

10 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?

Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

11 Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,

nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.

12 Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun a óo ṣe akin,

nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *