Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 6

Adura nígbà ìyọnu

1 OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;

má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà.

2 Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,

OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun.

3 Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,

yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?

4 OLUWA, pada wá gbà mí,

gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

5 Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.

Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú?

6 Ìkérora dá mi lágara:

ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;

tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù.

7 Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,

agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá.

8 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi,

nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi.

9 OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi,

OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi.

10 Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi;

ìdààmú ńlá yóo bá wọn,

wọn óo sá pada,

ojú yóo sì tì wọ́n lójijì.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *