Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 58

Kí Ọlọrun jẹ Ìkà níyà

1 Ǹjẹ́ ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe tọ̀nà, ẹ̀yin aláṣẹ? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan ní ọ̀nà ẹ̀tọ́?

2 Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò,

iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé.

3 Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà,

láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe,

tí wọn ń purọ́.

4 Wọ́n ní oró bí oró ejò,

wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀,

5 kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè,

tabi ìpè adáhunṣe.

6 Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun;

OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun.

7 Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi;

kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.

8 Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi,

ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí.

9 Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀;

ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ.

10 Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké,

yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú.

11 Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé,

“Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo;

nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *