Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 5

Adura Ààbò

1 Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA;

kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi.

2 Fetí sí igbe mi,

Ọba mi ati Ọlọrun mi,

nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.

3 OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀,

ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ;

èmi óo sì máa ṣọ́nà.

4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú;

àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé.

5 Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ;

o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi.

6 O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run;

OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn.

7 Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

èmi óo wọ inú ilé rẹ;

n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ.

8 OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi;

jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi.

9 Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn;

ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn.

Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;

ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn.

10 Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n;

jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú.

Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn,

nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11 Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn,

kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae.

Dáàbò bò wọ́n,

kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ.

12 Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo;

ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *