Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 4

Igbẹkẹle OLUWA

1 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,

Ọlọrun mi olùdániláre.

Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,

ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi.

2 Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀,

tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri?

3 Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀,

OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

4 Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀;

ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín,

kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.

5 Ẹ rú ẹbọ òdodo,

kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

6 Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?”

OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára.

7 Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn mi

ju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè.

8 N óo dùbúlẹ̀, n óo sì sùn ní alaafia,

nítorí ìwọ OLUWA nìkan ni o mú mi wà láìléwu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *