Ẹ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀
1 N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà;
ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.
2 OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;
kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.
3 Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,
ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!
4 Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,
ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù.
5 Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀;
ojú kò sì tì wọ́n.
6 Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀,
ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7 Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,
a sì máa gbà wọ́n.
8 Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA!
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í!
9 Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀,
nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀!
10 Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní,
ebi a sì máa pa wọ́n;
ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWA
kò ní ṣe aláìní ohun rere kankan.
11 Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi,
n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA.
12 Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín,
tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn,
tí ó fẹ́ pẹ́ láyé?
13 Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú,
ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde.
14 Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe;
ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀.
15 OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo,
Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn.
16 OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára,
láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé.
17 Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́,
a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn.
18 OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́,
a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.
19 Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀;
ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn.
20 A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́;
kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn.
21 Ibi ni yóo pa eniyan burúkú;
a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi.
22 OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada;
ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi.