Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 29

Agbára OLUWA ninu ìjì

1 Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA,

ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ.

2 Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀,

ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀.

3 À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun,

Ọlọrun ológo ń sán ààrá,

Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi.

4 Ohùn OLUWA lágbára,

ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá.

5 Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari,

OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni.

6 Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù,

ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó.

7 Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá.

8 Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀;

OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi.

9 Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí,

a máa wọ́ ewé lára igi oko;

gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀.

10 OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi;

OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae.

11 OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára;

OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *