Àyànfẹ́ Ọlọrun
1 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù
tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?
2 Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,
àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,
wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.
3 Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já
kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;
OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.
5 Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,
yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,
6 Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ,
ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.”
7 N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;
Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,
lónìí ni mo bí ọ.
8 Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè,
gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ.
9 Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn,
o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n;
ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.
11 Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA,
ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì.
12 Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú,
kí ó má baà pa yín run lójijì;
nítorí a máa yára bínú.
Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.