Ọlọrun Alágbára
1 Ẹ yin OLUWA!
Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa;
nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́.
2 OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu;
òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ.
3 Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu,
ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn.
4 Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀,
òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ.
5 OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọ
òye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n.
6 OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró,
òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
7 Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA,
ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa.
8 Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run,
ó pèsè òjò fún ilẹ̀,
ó mú koríko hù lórí òkè.
9 Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ,
tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké.
10 Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí,
kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà.
11 Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
12 Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!
Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!
13 Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,
ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.
14 Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,
ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.
15 Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,
àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá.
16 Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,
ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.
17 Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,
ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?
18 Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,
ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.
19 Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,
ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.
20 Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,
wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.
Ẹ yin OLUWA!