Abániṣé ni OLUWA
1 Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé,
asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ.
Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú,
asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de.
2 Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu,
kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn.
Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ;
nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.
3 Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ;
òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.
4 Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni.
5 Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn.
Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè.