Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 108

Adura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá

1 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun

ọkàn mi dúró ṣinṣin.

N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.

Jí, ìwọ ọkàn mi!

2 Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu!

Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu,

3 OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan,

n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

4 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,

òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

5 Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun,

kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé.

6 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,

fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn.

7 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,

ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,

n óo sì pín àfonífojì Sukotu.

8 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase.

Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,

Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

9 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,

lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé,

n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.”

10 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?

Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?

11 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?

Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́.

12 Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,

nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.

13 Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin;

nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *