Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni
1 Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní:
2 “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀,
ṣé kò ní bí ọ ninu?
Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí?
3 O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan,
o ti fún aláìlera lókun.
4 O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró,
ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára.
5 Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́,
o kò ní sùúrù;
Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ.
6 Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ?
Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?
7 “Ìwọ náà ronú wò,
ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí?
Tabi olódodo kan parun rí?
8 Bí èmi ti rí i sí ni pé,
ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè,
tí ó sì gbin wahala,
yóo kórè ìyọnu.
9 Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run,
ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.
10 Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun,
ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù,
ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.
11 Kinniun alágbára a máa kú,
nítorí àìrí ẹran pa jẹ,
àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.
12 “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létí
mo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.
13 Ninu ìran lóru,
nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,
14 ìbẹ̀rùbojo mú mi,
gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.
15 Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi,
gbogbo irun ara mi sì dìde.
16 Ó dúró jẹ́ẹ́,
ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí.
Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró;
gbogbo nǹkan parọ́rọ́,
nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,
17 ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?
Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?
18 Nígbà tí ó jẹ́ pé,
Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀,
a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;
19 mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ,
tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀,
tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.
20 Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀
kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́,
wọn a parun títí lae
láìsí ẹni tí yóo bìkítà.
21 Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀,
ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’