1 “Nígbà tí mo gbọ́, ọkàn mi wárìrì,
ó sì fò sókè ní ipò rẹ̀.
2 Gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ń dún bí ààrá,
ati ariwo tí ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.
3 Ó rán mànàmáná rẹ̀ sí wọn jákèjádò ojú ọ̀run,
títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
4 Lẹ́yìn náà, a gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
ó sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá rẹ̀,
bí ìgbà tí ààrá bá sán,
sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúró
bí àwọn eniyan ti ń gbóhùn rẹ̀.
5 Ohùn Ọlọrun dún bí ààrá tìyanu-tìyanu,
a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
6 Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli,
ati ọ̀wààrà òjò.
7 Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò,
kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.
8 Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ,
wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́.
9 Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀,
òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.
10 Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá,
gbogbo omi inú odò sì dì.
11 Ó fi omi kún inú ìkùukùu,
ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.
12 Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀,
láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.
13 Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀,
bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀,
tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14 “Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu,
dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.
15 Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ,
tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?
16 Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀,
iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;
17 ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́
nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?
18 Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ,
kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán?
19 Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ,
a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀,
nítorí àìmọ̀kan wa.
20 Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni?
Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì?
21 “Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run
nígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma,
nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.
22 Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ,
ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.
23 Àwámárìídìí ni Olodumare–
agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀.
24 Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀,
kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.”