Categories
JOBU

JOBU 35

1 Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,

2 “Jobu, ṣé o rò pé ó tọ̀nà,

kí o máa sọ pé, ‘Ọ̀nà mi tọ́ níwájú Ọlọrun?’

3 Kí o tún máa bèèrè pé, ‘Anfaani wo ni mo ní?

Tabi kí ni mo fi sàn ju ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ lọ?’

4 N óo dá ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lóhùn.

5 Gbójú sókè kí o wo ojú ọ̀run,

ati àwọn ìkùukùu tí ó wà lókè.

6 Bí o bá dẹ́ṣẹ̀, kò ṣe Ọlọrun ní àìrójú,

bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bá pọ̀, kò jámọ́ nǹkankan fún un.

7 Bí o bá jẹ́ olódodo,

kí ni ó dà fún Ọlọrun,

tabi kí ni ó ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ?

8 Àwọn eniyan burúkú bíì rẹ, ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè pa lára,

àwọn ọmọ eniyan ni òdodo rẹ sì lè jẹ́ anfaani fún.

9 “Àwọn eniyan ń kígbe nítorí ọpọlọpọ ìnira,

wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́,

nítorí àwọn alágbára ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

10 Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó bèèrè pé,

‘Níbo ni Ọlọrun Ẹlẹ́dàá mi wà,

tíí fún ni ní orin ayọ̀ lóru,

11 ẹni tí ó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ju àwọn ẹranko lọ,

Ó sì fún wa ní ọgbọ́n ju àwọn ẹyẹ lọ?’

12 Wọ́n kígbe níbẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lóhùn,

nítorí ìgbéraga àwọn eniyan burúkú.

13 Dájúdájú Ọlọrun kì í gbọ́ igbe asán,

Olodumare kò tilẹ̀ náání rẹ̀.

14 Kí á má tilẹ̀ sọ ti ìwọ Jobu, tí o sọ pé

o kò rí i,

ati pé ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀,

o sì ń dúró dè é!

15 Ṣugbọn nisinsinyii, nítorí pé inú kì í bí i kí ó jẹ eniyan níyà,

bẹ́ẹ̀ ni kò ka ẹ̀ṣẹ̀ kún lọ títí.

16 Jobu kàn ń la ẹnu,

ó sì ń sọ̀rọ̀ lásán ni.

Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀, ṣugbọn kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *