Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 47

Iṣẹ́ tí OLUWA Rán sí Àwọn Ará Filistia

1 OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa,

2 Ó ní,

“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,

yóo di àgbàrá tí ó lágbára;

yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,

yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.

Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

3 Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún,

tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré,

tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo,

Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n,

nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ;

4 nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia,

ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni.

Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run,

àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori.

5 Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun.

Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

6 Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA,

yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi?

Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’

7 Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe?

OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *