1 Má lérí nípa ọ̀la,
nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
2 Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ,
jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde,
kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára.
3 Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n,
ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ.
4 Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ,
ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?
5 Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.
6 Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́;
ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.
7 Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú,
ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn,
lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8 Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀,
dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.
9 Òróró ati turari a máa mú inú dùn,
ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.
10 Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;
má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.
Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.
11 Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn,
kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.
12 Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́,
ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.
13 Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,
kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀,
tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.
14 Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀,
tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀,
kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè.
15 Iyawo oníjà dàbí omi òjò,
tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró;
16 ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kun
dàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró,
tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.
17 Bí irin ti ń pọ́n irin,
bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.
18 Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ,
ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.
19 Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.
20 Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn,
bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.
21 Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò,
ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.
22 Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó,
kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà,
ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
23 Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí,
sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;
24 nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí,
kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran.
25 Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù,
tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé,
26 o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ,
o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀.
27 O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu,
ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu.