1 Orísun omi ni ọkàn ọba lọ́wọ́ OLUWA,
ibi tí ó bá wu Oluwa ni ó ń darí rẹ̀ sí.
2 Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó dára lójú ara rẹ̀,
ṣugbọn ọkàn ni OLUWA ń wò.
3 Kí eniyan ṣe òdodo ati ẹ̀tọ́,
sàn ju ẹbọ lọ lójú OLUWA.
4 Bíi fìtílà ẹni ibi ni gbígbé ojú gangan ati ìgbéraga,
ẹ̀ṣẹ̀ sì ni wọ́n.
5 Dájúdájú èrò ẹni tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóo yọrí sí ọ̀pọ̀,
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń kánjú jù kò ní ní ànító.
6 Fífi èké kó ìṣúra jọ
dàbí lílé ìkùukùu, ó sì jẹ́ tàkúté ikú.
7 Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù,
nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́.
8 Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,
ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́.
9 Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,
ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.
10 Ibi ni ọkàn eniyan burúkú máa ń fẹ́,
àwọn aládùúgbò rẹ̀ kì í sìí rí ojurere rẹ̀.
11 Ìjìyà ẹlẹ́yà a máa mú kí òpè gbọ́n,
tí a bá ń kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo ní ìmọ̀ sí i.
12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé eniyan burúkú,
eniyan burúkú sì bọ́ sinu ìparun.
13 Ẹni tí ó kọ etí dídi sí igbe talaka,
òun náà yóo kígbe, ṣugbọn kò ní rí ẹni dá a lóhùn.
14 Ẹ̀bùn tí a fúnni ní kọ̀rọ̀ a máa paná ibinu,
àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a tì bọ abẹ́ aṣọ a máa paná ìjà.
15 Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn,
ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi.
16 Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òye
yóo sinmi láàrin àwọn òkú.
17 Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka,
ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́.
18 Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibi
tíì bá dé bá olódodo.
Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú.
19 Ó sàn láti máa gbé ààrin aṣálẹ̀,
ju kí eniyan máa bá oníjà ati oníkanra obinrin gbé lọ.
20 Ní ilé ọlọ́gbọ́n ni à á tí ń bá nǹkan olówó iyebíye,
ṣugbọn òmùgọ̀ a máa ba tirẹ̀ jẹ́.
21 Ẹni tí ń lépa òdodo ati àánú
yóo rí ìyè, òdodo, ati iyì.
22 Ọlọ́gbọ́n a máa gba ìlú àwọn alágbára
a sì wó ibi ààbò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lulẹ̀.
23 Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́
pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu.
24 “Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga,
tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí.
25 Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á,
nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.
26 Eniyan burúkú a máa ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ìgbà,
ṣugbọn olódodo ń fúnni láìdáwọ́dúró.
27 Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú,
pàápàá tí ó bá mú un wá pẹlu èrò ibi.
28 Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí èké yóo di asán,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fetí sílẹ̀ ni a óo gbàgbọ́.
29 Eniyan burúkú a máa lo ògbójú,
ṣugbọn olóòótọ́ máa ń yẹ ọ̀nà ara rẹ̀ wò.
30 Kò sí ọgbọ́n, tabi òye, tabi ìmọ̀,
tí ó lè dojú kọ OLUWA kí ó mókè.
31 Eniyan a máa tọ́jú ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,
ṣugbọn OLUWA ló ni ìṣẹ́gun.