Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 13

1 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,

ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí.

2 Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,

ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan.

3 Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́,

ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.

4 Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i,

ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.

5 Olóòótọ́ a máa kórìíra èké,

ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.

6 Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́,

ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.

7 Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀,

bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan,

níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka,

ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

8 Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada,

ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí.

9 Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,

ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.

10 Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,

ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.

11 Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,

ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.

12 Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,

ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.

13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,

ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.

14 Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè

a máa yọni ninu tàkúté ikú.

15 Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere,

ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.

16 Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo,

ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.

17 Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala,

ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.

18 Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn,

ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì.

19 Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀,

ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀.

20 Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.

21 Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire.

22 Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,

ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.

23 Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde,

ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ.

24 Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí.

25 Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn,

ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *