Categories
AISAYA

AISAYA 53

1 Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́?

Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn?

2 Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé

ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ.

Ìrísí rẹ̀ kò dára,

ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra,

bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan.

3 Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,

wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;

ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.

Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.

A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.

4 Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,

ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;

sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,

tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

5 Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa,

wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;

ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,

nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.

6 Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan,

olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,

OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.

7 Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú,

sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,

wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,

ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.

8 Wọ́n mú un lọ tipátipá,

lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,

ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé

wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,

ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?

9 Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú,

wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi,

kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

10 Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára,

ó sì fi í sinu ìbànújẹ́,

nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

yóo fojú rí ọmọ rẹ̀,

ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn.

Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.

11 Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀,

yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;

nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo,

yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre,

yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

12 Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín,

láàrin àwọn eniyan ńlá,

yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun,

nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú,

wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan,

ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *